Nípa

A dá àwọn Olùwádìí COVID ti ìlú Chicago láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ènìyàn láti ráye sí ìwádìí àmúdójúìwọ̀n fún ìlú Chicago àti Cook County ní àsìkò àjàkálẹ̀ àrùn tókárí ayé ti àìsàn corona.

A ṣe ojú ìwé ayélujára yìí, a sì ń tọ́jú ẹ̀, láti ọwọ́ City Bureau, tó jẹ́ ilé iṣẹ́ aláìlérè, aláìṣègbè ti iṣẹ́ ìròyìn tó wà ní Gúsù Chicago. Iṣẹ́ wa ni láti mú àwọn agbègbè papọ̀ láti ṣe ìpèsè ilé iṣẹ́ ìkéde ìròyìn tó péye tó sì nípa.

Sáìtì yìí ni a ó máa múdójúìwọn lóòrèkóòrè, a ó sì máa fi àwọn èdè míì síi láìpẹ́. Tí o bá fẹ́ fi àwọ oun èlò míì tó wa létí, fi àyípadà hàn wá, tàbí tó wa létí, lọ síbí tàbí kí o ṣe ìfiránṣẹ́ ímeèlì sí info@citybureau.org.

Ṣé o fẹ́ ráyè sí ẹ̀rọ àmúlò yí nípasẹ̀ ìfọ̀rọ̀ráńṣẹ́?

Kọ "covid" sí (312) 436-2280 o lè gba àtòkọ àwọn ìwádìí lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ẹ.

O ń ronú nípa lílo ayélujára?

Ìgbìmọ̀ Ìlú (City Bureau) ń gbìmọ̀pọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ agbègbè láti jẹ́ kí àwọn agbègbè gba àlàyé ní kíkún. Gẹ́gẹ́ bí ara àlàyé ti iṣẹ́ agbese Aid Network, a ń pe àwọn ará agbègbè tí wọn ò ní ààyè láti lo ayélujára púpọ̀ láti bá wọn ṣàyẹ̀wò àgbàsọ, dáhùn ìbéèrè àti láti so àwọn ènìyàn pọ̀ pẹ̀lú oníròyìn agbègbè. Tí o bá fẹ́ darapọ̀ mọ́ Information Aid Network, fi orúkọ rẹ sílẹ̀ síbí.

Ìdúpẹ́

A dúpẹ́ lọ́wọ́ ìdarapọ̀ àwọn alábàáṣepọ̀ ti agbègbè wa bíi Chicago United for Equity, Rohingya Cultural Center, West Side United, Organized Communities Against Deportations, The Middle Eastern Immigrant àti Refugee Alliance (MIRA), Austin Coming Together, Raise Your Hand, The Goodie Shop àti The Firehouse Community Arts Center. Àwọn ohun èlò ni a kọ́jọpọ̀ láti àwọn ìwádìí ògidì láti ìgbìmọ̀ atẹ̀ròyìn City Bureau nítorí àwọn àkọsílẹ̀ tí ó wà tẹ́lẹ̀ tí a ṣẹ̀dá nípasẹ̀ ti ìlú Chicago (City of Chicago), Block Club Chicago, South Side Weekly, West Side United, Accion pẹ̀lú ICIRR.